20/08/2024
*ÌBÍNÚ*
* Àìsàn burúkú ni ìbínú jẹ́...
* Kò dára bẹ́ẹ̀ ni kò sunwọ̀n....
* Ìbínú yára pànìyàn...
* Ìbínú rán ènìyàn lọ sí ibi tí kò tọ́....
* Ìbínú kìí tún nǹkan ṣe ó máa ń ba nǹkan jẹ́ ni....
* Ohun tí èèyàn ti sé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún...
* Ìbínú a máa bàájẹ́ ní ọjọ́ kan...
* Ìbínú a máa lé olóore jìnà síni...
* Inú bíbí a máa fa wàhálà síni lọ́run...
* Ọ̀pọ̀ èèyàn ni inú bíbí ti sìn dé ọgbà ẹ̀wọ̀n...
* Ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó ló ti foríṣọ́pọ́n ní pa inú bíbí
* Ọ̀pọ̀ obìnrin ló ti lọ dálémoṣú nípasẹ̀ inú bíbí
* Ọ̀pọ̀ ọkùnrin ló ti di Àpọ́n ọ̀sán gangan ní pa àìsàn inú àbíjù....
* Ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ ìjọba ni wọ́n ti fún ní ìwé gbé lé ẹ nípasẹ̀ inú bíbí
* Ọ̀pọ̀ oníșẹ́ ọwọ́ ló ti lé àwọn oníbáárà ní pa aṣọ ìbínú tí ó gbé wọ̀...
* Bí ìwọ náà bá wá jẹ́ ẹni tí ó máa ń bínú jù...
* Yálà ọkùnrin ni Ọ́ tàbí obìnrin.... Yára lọ wá àtúnṣe sí ọ̀rọ̀ rẹ...
* Kí ìwọ náà lọ ní sùúrù bí ilẹ̀....
* Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀gbin ni à ń ṣe sí ilẹ̀.... Síbẹ̀ omi tómọ́ ló ń sun jáde fún wa...
* Gbogbo ibikíbi tí o bá ń lọ máa rántí pé..
* Ìbínú kìí fa ire mọ́ra...
*SÙÚRÙ KÌÍ PỌ̀JÙ ÀYÀFI TÍ KÒ BÁ NÍ TÓ...*
OHUN MẸTA MẸTA TO ṢE KOKO NINU AYE ỌMỌ ENIYAN , TO YẸ KI A MA ṢE AKIYESI RẸ NINU AYE WA.*
*AGBỌDỌ NI AWỌN NKAN MẸTA WỌNYI.*
1. Otitọ
2. Ìgbàgbọ
3. Iwà Rere
*JA ARA RE GBA LỌWỌ NKAN MẸTA WỌNYI:*
1. Igberaga
2. Iyànjẹ
3. Gbese jijẹ
*AGBỌDỌ NI IKAPA LORI NKAN MẸTA WONYI:*
1. Ahọn
2. Ibìnù
3. Ife inu Ẹni
*YẸRA FUN NKAN MẸTA WỌNYI:*
1. Iwà Buburu
2. Biba Ọmọlàkejì jẹ lẹyìn.
3. Owu
*AGBỌDỌ NI NKAN META WONYI:*
1. Imọ
2. Iwà
3. If'okànsìn
*JẸ KI NKAN MẸTA WỌNYI WA NI MIMỌ TONITONI NI GBOGBO IGBA:*
1. Ara
2. Aṣọ
3. Ọkàn
*MA ṢE IRANTI NKAN MẸTA WỌNYI LOOREKOORE:*
1. Iku
2. Oore ti enìyàn ba Ṣe fun ọ
3. Amọràn Agbà
*Ẹ ṢE ÀTÚNṢE NI ONI KO TO DI WI PE O PE JU.
IRE🙌🙌🙌🙌🙌🙌🙌🙌🙌🙌🙌🙌🙌🙌